Hymn 130 – ALLELUYAH! orin t'o dun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "ALLELUYAH! orin t'o dun" (C&S Hymn #130, Yoruba). 1. ALLELUYAH! orin t'o dun, Ohun ayọ ti ki ku; Alleluyah! orin…

Hymn 130 – ALLELUYAH! orin t'o dun | C&S Yoruba Hymnary
1. ALLELUYAH! orin t'o dun, Ohun ayọ ti ki ku; Alleluyah! orin didun, T'awọn t'o wa l'ọrun fẹ; N'ile ti Ọlọrun mi ń gbe, Ni wọn n kọ tọsan-toru. 2. Alleluyah! Ijọ ọrun, Ẹ le kọrin ayọ na; Alleluyah! orin 'sẹgun, Yẹ awọn t'a rapada; Awa ero at'alejo, di Iyin wa ko nilari. 3. Alleluyah! orin ayọ, Lo yẹ wa nigba gbogbo; Alleluyah! ohun aro, Da mọ orin ayọ wa; Gbat'a wa layé osi yi, A ni gbawẹ f'ẹsẹ wa. 4. Iyin dapọ m'adua wa, Gbọ tiwa, Mẹtalọkan; Mu wa de 'waju Rẹ l'ayọ, K'a f'Ọdaguntan t'a pa; K'a le ma kọ Alleluyah, Nibẹ lai ati lailai. AMIN

Hymn 130 – ALLELUYAH! orin t'o dun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia