Hymn 132 – EYIN Angel orun, e bu sayo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "EYIN Angel orun, e bu sayo" (C&S Hymn #132, Yoruba). 1. ẸYIN Angẹl ọrun, ẹ bu sayọ, Kérúbù Séráfù ayé gberin; K'awa ko…

Hymn 132 – EYIN Angel orun, e bu sayo | C&S Yoruba Hymnary
1. ẸYIN Angẹl ọrun, ẹ bu sayọ, Kérúbù Séráfù ayé gberin; K'awa ko ke Hosanna, Ka si foribalẹ fun, Mẹtalọkan Olore. Ka jọ ho, ka jọ yọ, Nitori Baba pe wa sinu agbo, Ka jọ ho, ka jọ yọ, Ka si le n'iwa mimo, Ti y'o mu wa de Kenaan. 2. A dupẹ t'Ọlọrun wa pẹlu wa, A dupẹ pe Maikẹli jẹ tiwa; Ẹ jẹ ka jo damuso, Ka si yin Baba loke, Ti O da wa si d'oni. 3. Oluso-Àgùntàn Israeli, Iwọ ti ki sun, ti ki togbe; Masai fi ọpa Rẹ tọ, Awọn to sun ninu wa, K'ifẹ Rẹ ko le ma tan. 4. Baba, masai se wa l'aguntan Rẹ, Ti yoo ma gbọ ipe Oluwa Rẹ, Ma jẹ ka sọnu kuro, Ninu ọna toro na, Ti o lọ si ibi iye. 5. f Alabukun fun n'iwọ ẹni ti, O ń pese fun awọn ẹni igbani; Jọwọ ma sai be wa wo, Pẹlu ẹbun rere Rẹ, K'awa le sin Ọ dopin. AMIN

Hymn 132 – EYIN Angel orun, e bu sayo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia