Hymn 120 – JI, okan mi, dide layo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "JI, okan mi, dide layo" (C&S Hymn #120, Yoruba). 1. JI, ọkan mi, dide layọ, Kọrin iyin Olugbala; Ọla Rẹ bere orin mi,…

Hymn 120 – JI, okan mi, dide layo | C&S Yoruba Hymnary
1. JI, ọkan mi, dide layọ, Kọrin iyin Olugbala; Ọla Rẹ bere orin mi, 'Seun ifẹ Rẹ ti pọ to! 2. O ri mo segbe n'isubu, Sibẹ, O fẹ mi l'afẹtan; O yọ mi ninu osi mi, 'Seun ifẹ Rẹ ti tobi to! 3. Ogun ọta dide si mi, Ayé at'Esu n de'na mi, Oun n mu mi la gbogbo rẹ ja, 'Seun ifẹ Rẹ ti n'ipa to! 4. 'Gba 'yọnu de, b'awọsanma, T'o su dudu t'o n san ara; O duro ti mi larin rẹ, 'Seun ifẹ Rẹ ti dara to! 5. 'Gba gbogbo l'ọkan ẹsẹ mi, N fẹ ya lẹhin Oluwa mi; Sugbọn bi mo ti n gbagbe Rẹ, Iseun ifẹ Rẹ ki yẹ. 6. Mo fẹrẹ f'ayé silẹ na, Mo fẹ bọ lọw'ara iku; A! k'emi kẹhin mi kọrin Iseun ifẹ Rẹ n'iku. 7. Njẹ ki n fo lọ, ki n si goke, S'ayé imọlẹ titi lai; Ki n f'ayọ iyanu kọrin, Iseun ifẹ Rẹ lọrun. AMIN

Hymn 120 – JI, okan mi, dide layo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia