Hymn 119 – GBOGBO aye, gbe Jesu ga | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "GBOGBO aye, gbe Jesu ga" (C&S Hymn #119, Yoruba). 1. GBOGBO ayé, gbe Jesu ga, Angẹl, ẹ wolẹ fun; Ẹ mu ade Ọba Rẹ wa,…
1. GBOGBO ayé, gbe Jesu ga, Angẹl, ẹ wolẹ fun; Ẹ mu ade Ọba Rẹ wa, Se l'Ọba awọn Ọba. 2. Ẹ se l'Ọba, ẹyin Martyr, Ti n pe ni pẹpẹ Rẹ; Gbe gbongbon-igi Jesse ga, Se l'Ọba awọn Ọba. 3. Ẹyin iru-ọmọ Israel, Ti a ti rapada; Ẹ ki ẹni t'o gba yin la, Se l'Ọba awọn Ọba. 4. Gbogbo eniyan ẹlẹsẹ, Ranti 'banujẹ yin; Ẹ tẹ 'kogun yin s'ẹsẹ Rẹ, Se l'Ọba awọn Ọba. 5. Ki gbogbo orilẹ-ede, Ni gbogbo agbayé; Ki wọn ki, ―Kabiyesilẹ‖, Se l'Ọba awọn Ọba. 6. A bale pẹl'awọn t'ọrun, Lati ma juba Rẹ; K'a ba le jọ jumọ kọrin, Se l'Ọba awọn Ọba. AMIN
Hymn 119 – GBOGBO aye, gbe Jesu ga | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia