Hymn 118 – EWE ti Oba orun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EWE ti Oba orun" (C&S Hymn #118, Yoruba). 1. EWE ti Ọba ọrun, Kọrin didun be ti n lọ; Kọrin 'yin Olugbala, Ologo 'nu…
1. EWE ti Ọba ọrun, Kọrin didun be ti n lọ; Kọrin 'yin Olugbala, Ologo 'nu isẹ Rẹ. A n lọ'le sọdọ Ọlọrun Lọna t'awọn Baba rin; Wọn si n yọ; nisinsin yii, Ayọ wọn l'awa o ri. 2. A n lọ sọdọ Ọlọrun, Lọna t'awọn Baba rin; Wọn si n yọ; nisinsin yii, Ayọ wọn l'awa o ri. 3. Kọrin agbo kekere, Ẹ o sinmi n'itẹ Rẹ; 'Bit'a pese 'joko yin, Ibẹ si n' ijọba yin. 4. W'Oke, ọmọ imọlẹ, Ilu Sion wa lọọkan; Ibẹ n'ile wa titi, Ibẹ l'a o r'Oluwa. 5. Kérúbù, tẹsiwaju, Séráfù, ma jafara, Kristi Ọmọ Baba n wi, Pe laifoya ka ma lọ. 6. Jesu, a n lọ l'asẹ Rẹ, A kọ'hun gbogbo sile; Iwọ ma j'amọna wa, A o si ma ba ọ lọ. 7. A f'ogo fun Baba wa, A f'ogo fun Ọmọ Rẹ; Ogo ni f'Ẹmi Mimọ , Mu wa de'le ayọ naa. A n lọ'le sọdọ Ọlọrun Lọna t'awọn Baba rin; Wọn si n yọ; nisinsin yii, Ayọ wọn l'awa o ri. AMIN
Hymn 118 – EWE ti Oba orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia