Hymn 117 – E WOLE f'Oba Ologo julo | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E WOLE f'Oba Ologo julo" (C&S Hymn #117, Yoruba). 1. Ẹ WOLẸ f'Ọba Ologo julọ, Ẹ kọrin ipa ati ifẹ Rẹ; Alabo wa ni…

Hymn 117 – E WOLE f'Oba Ologo julo | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹ WOLẸ f'Ọba Ologo julọ, Ẹ kọrin ipa ati ifẹ Rẹ; Alabo wa ni at'Ẹni Igbani, O n gbe 'nu ogo, Elẹru ni iyin. 2. Ẹ sọ t'ipa Rẹ, ẹ sọ t'ore Rẹ, 'Molẹ l'asọ Rẹ, kọbi Rẹ ọrun, cr Ara ti n san ni kẹkẹ 'binu Rẹ jẹ, Ipa ọna Rẹ ni a ko si le mọ. 3. Ayé yi pẹlu ẹkun 'yanu rẹ, Ọlọrun agbara Rẹ l'o da wọn; O fi idi rẹ mulẹ ko si le yi, O si f'okun se asọ igunwa. 4. Ẹnu ha le sọ ti itọju Rẹ? Ninu afẹfẹ, ninu imọlẹ; Itọju Rẹ wa nin' odo t'o n san, O si wa ninu iri ati ojo. 5. Awa erupẹ, aw'alailera, 'Wọ l'a gbẹkẹle, O ki o da ni; Anu rẹ rọnu, o si le de opin, Ẹlẹda, Alabo, Olugbala wa. 6. 'Wọ Alagbara, Onifẹ julọ, B'awọn angẹli to n yin Ọ loke, Bẹ l'awa ẹda Rẹ, niwọn t'a le se, A o ma juba Rẹ, a o ma yin Ọ. AMIN

Hymn 117 – E WOLE f'Oba Ologo julo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia