Hymn 121 – AWA dupe o lowo Baba wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AWA dupe o lowo Baba wa" (C&S Hymn #121, Yoruba). 1. AWA dupẹ o lọwọ Baba wa (2ce) Ti ru ọjọ oni t'o fi soju ẹmi Jẹ…
1. AWA dupẹ o lọwọ Baba wa (2ce) Ti ru ọjọ oni t'o fi soju ẹmi Jẹ k'a seyi s'amọdun, Jọwọ jẹ ki ire wọle wa o, Ninu ọdun t'a bọ si. Jẹ ki' ire k'o le wọ'le gbogbo wa (2ce) Loni o (2ce) Awa dupẹ lọwọ Jehovah loke ọrun (2ce) 2. Ta ni fẹ isẹgun (2ce) Emi fẹ Emi fẹ isẹgun k'o na'wọ rẹ soke Emi fẹ isẹgun Lori ajẹ oso Emi fẹ isẹgun Lori ọta ile Emi fẹ isẹgun Lori ọta 'bi'sẹ Emi fẹ isẹgun Lori ọta ilu Emi fẹ isẹgun Ati lori 'pọnju Emi fẹ isegun Balogun wa ti de loni o (2ce) Lati sẹgun fun gbogbo wa (2ce) Awa dupẹ lọwọ Jehovah loke ọrun (2ce) 3. Ta ni n fẹ abo (2ce) Emi fẹ Ẹni fẹ abo k'o na'wọ rẹ soke Emi fẹ abo Lori ọmọ ẹgbẹ Emi fẹ abo Lori awọn ẹbi Emi fẹ abo Lori awọn obinrin Emi fẹ abo Lori awọn ọmọde Emi fẹ abo Lori awọn agba Emi fẹ abo Lori awọn ọkunrin Emi fẹ abo Alabo wa ti de loni o (2ce) Lati dabo bo gbogbo wa (2ce) Awa dupẹ lọwọ Jehovah loke ọrun (2ce) 4. Tani fẹ pese (2ce) Emi fẹ Ẹni fẹ ipese k'o na'wọ rẹ soke Emi fẹ ipese Se ipese owo Emi fẹ ipese Ati pese ọmọ Emi fẹ ipese Ati t'alafia Emi fẹ ipese Ati pese isẹ Emi fẹ ipese Olupese wa ti de loni o (2ce) Lati pese fun gbogbo wa (2ce) Awa dupẹ lọwọ Jehovah loke ọrun (2ce) 5. Ta ni fẹ ri Jesu (2ce) Emi fẹ, Ẹni fẹ ri Jesu ko na'wọ re soke Emi fe ri Jesu K'o le wa bukun fun wa Emi fẹ ri Jesu K'o le fun wa lagbara Emi fẹ ri Jesu K'a le se 'fẹ Rẹ d'opin Emi fẹ ri Jesu K'awa le gb'ade ogo Emi fẹ ri Jesu Jesu Olugbala wa ti gunwa sihin (2ce) lati wa bukun gbogbo wa (2ce) Awa dupẹ lọwọ Jehovah loke ọrun (2ce) 6. Kilo yẹ wa loni o (2ce) A f'ọpẹ Fun gbogbo awọn Ore t'Oluwa se fun wa, E f'ope f'Oluwa Ẹyin Agba Meje ― ― ― Ẹyin Asiwaju ― ― ― Committee ọkunrin ― ― ― Committee obinrin ― ― ― Ọmọ Ogun Kristi ― ― ― Irawọ Owurọ ― ― ― Ẹgbẹ Ifẹloju ― ― ― F'ogo Ọlọrun han ― ― ― Ẹyin Ẹgbẹ Mary ― ― ― Ẹyin Ẹgbẹ Marta ― ― ― Ayaba Esta ― ― ― Ẹyin Ẹgbẹ Roda ― ― ― Awọn Akọrin wa ― ― ― Ẹyin ọmọ Ijọ ― ― ― Fun Ore Isẹgun ― ― ― Fun ibukun Gbogbo ― ― ― Nitori o da wa si ― ― ― Pe o ti gbọ ti wa ― ― ― Ọpẹ lo yẹ Baba wa loni (2ce) T'O wa sure fun…
Hymn 121 – AWA dupe o lowo Baba wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia