Hymn 113 – Oba iyanu to wa mi ri | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Oba iyanu to wa mi ri" (C&S Hymn #113, Yoruba). 1. Ọba iyanu to wa mi ri, N ó gb'agogo iyin y'ayé ka, N ó fi iyin…
1. Ọba iyanu to wa mi ri, N ó gb'agogo iyin y'ayé ka, N ó fi iyin Atobiju han. Oluwa ọpẹ ni fun Ọ, Fun ore-ọfẹ to fi pe mi, Jesu di mi mu titi d'opin, Ki n le jọba pẹlu Rẹ l'oke. 2. Iru 'fẹ ti Jesu fi pe mi, Ohun iyanu l'o jẹ fun mi, Ọna ti Jesu gba fi pe mi, Ọna ara l'o tun jẹ fun mi. 3. Ọpẹ wo l'awa le fi fun Ọ? Iwọ Ọba Ijọ Kérúbù, Fun 'sẹgun abo rẹ larin wa, Fun anu at'ore Rẹ gbogbo. 4. Iwọ ti o gba ọpẹ Noah, Gb'ọpẹ iyin t'a mu wa fun Ọ, Iwọ ti o gba ọrẹ Abel, Ma jẹ k' ọpẹ wa k'o di 'bajẹ. 5. Ijọ Kérúbù ati Séráfù, Ẹ ho, ẹ yọ si Ọba Ọrun, Fun'sẹ Iyanu Rẹ larin wa, Fun ore Rẹ alailosuwọn. 6. Ayọ ni fun wa l'ọjọ oni, A f'ogo fun Baba at'Ọmọ, A f'ogo fun Ọ Ẹmi Mimọ , Ọlọjọ oni gba ọpẹ wa. Oluwa ọpẹ ni fun Ọ, Fun ore-ọfẹ to fi pe mi, Jesu di mi mu titi d'opin, Ki n le jọba pẹlu Rẹ l'oke. AMIN
Hymn 113 – Oba iyanu to wa mi ri | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia