Hymn 112 – OLORUN Eleda wa, awa n yin O | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN Eleda wa, awa n yin O" (C&S Hymn #112, Yoruba). 1. ỌLỌRUN Ẹlẹda wa, awa n yin Ọ, Fun ore nla yi (2ce) Fun dida…
1. ỌLỌRUN Ẹlẹda wa, awa n yin Ọ, Fun ore nla yi (2ce) Fun dida to da Ijọ nla yi silẹ, Fun 'gbala eniyan dudu. Ọlọrun jọwọ mu wa yẹ, K'awa le wọ ijọba Rẹ, Ma jẹ ki Séráfù ati Kérúbù, Tun kuna Ijọba ọrun. 2. Jehovah Emmanueli awa dupẹ, T'o bẹbẹ fun wa (2ce) T'o si da Ẹgbẹ Séráfù yi silẹ, Ninu aginju ayé yi. 3. Awa mbẹ O fun Olori wa, Ọlọrun, Fun l'agbara Rẹ (2ce) Jẹ k'o le sisẹ Rẹ titi d'opin K'o gba'de t'O ti pese fun un. 4. Ọlọrun Daniel awa mbẹ Ọ, Masai gbọ ti wa (2ce) Ma jẹ k'a ri idanwo ti y'o fa wa, Pada si ohun atijọ. AMIN
Hymn 112 – OLORUN Eleda wa, awa n yin O | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia