Hymn 111 – E JE k'a yin Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E JE k'a yin Olorun wa" (C&S Hymn #111, Yoruba). 1. Ẹ JẸ k'a yin Ọlọrun wa, Ẹni t'O wa l'oke ọrun, T'O fi Ounjẹ fun…
1. Ẹ JẸ k'a yin Ọlọrun wa, Ẹni t'O wa l'oke ọrun, T'O fi Ounjẹ fun eniyan Ti O si fi fun ẹranko. 2. O si tẹ oju ọrun lọ, O da orun oun osupa, Isẹ ọwọ Rẹ n'irawọ, Iye wọn awa ko le ka. 3. O si da ara eniyan, O si fun wọn l'ẹmi pẹlu; O si da ni daradara, Bi o ti yẹ, bi 'ba ti wa. 4. Sugbọn eniyan dibajẹ, Wọn si bọ sinu buburu; Ere ẹsẹ ni wọn si n jẹ, Ni wahala ati n'iku. 5. f Sugbọn jẹ ka yin Ọlọrun, Oun fun wa ni Kristi Jesu; Lati wa awọn t'o ti nu, Ninu ẹsẹ ti wọn ti n rin. AMIN
Hymn 111 – E JE k'a yin Olorun wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia