Hymn 114 – Ninu gbogbo ayida aye | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Ninu gbogbo ayida aye" (C&S Hymn #114, Yoruba). 1. N'nu gbogbo ayida ayé, Ayọ oun wahala; Iyin Ọlọrun ni y'o ma, Wa…
1. N'nu gbogbo ayida ayé, Ayọ oun wahala; Iyin Ọlọrun ni y'o ma, Wa l'nu mi titi. 2. Gbe Oluwa ga pẹlu mi, Ba mi gb'ookọ Rẹ ga; p N'nu wahala, 'gba mo ke pe, O si yọ mi kuro. 3. f Ogun Ọlọrun wa yika, Ibugbe olootọ; Ẹni ti o ba gbẹkẹle, Yoo si ri 'gbala. 4. Sa dan ifẹ Rẹ wo lẹkan, Gbana 'wọ o mọ pe, Awọn t'o di ootọ rẹ mu, Nikan l'ẹni 'bukun. 5. Ẹ bẹru Rẹ, ẹyin mimọ, Ẹru miran ko si; Sa jẹ ki'sin Rẹ j'ayọ yin, Oun y'o ma tọju yin. AMIN
Hymn 114 – Ninu gbogbo ayida aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia