Hymn 108 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU ati Serafu" (C&S Hymn #108, Yoruba). 1. KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ fun irugbin rere s'ayé, Ẹyin l'a pe lati s'awọn Ti…

Hymn 108 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary
1. KÉRÚBÙ ati Séráfù, Ẹ fun irugbin rere s'ayé, Ẹyin l'a pe lati s'awọn Ti yoo pade Oluwa l'oke. Gbọ, gbọ, gbọ b'awọn Séráfù ti n ke, Gbọ, gbọ, gbọ b'awọn Kérúbù ti n ke Halleluyah, Halleluyah, Halleluyah, f'Ọba wa. 2. Onigbagbọ, ẹ ji giri, K'a fi iwa ẹsẹ s'ilẹ, K'a se ifẹ Oluwa wa, K'a le r'oju rere Ọlọrun. 3. Onigbagbọ, ẹ gb' adura, Ẹ fi ọkan funfun sisẹ, Ẹ gb'awẹ pẹlu iwa mimọ, Eyi ni Jesu wa se l'aye. 4. Ẹyin araye, ẹ tun aye se, Fun bibọ jesu Oluwa - K'ẹsẹ dinku, k'ajakalẹ arun, Ma ti wa lọ s'ọrun apadi. 5. Onigbagbọ bẹru Ọlọrun, Fẹran ọmọnikeji rẹ, Mase pẹgan mase binu, Ọlọrun adura rẹ. 6. Ọpọ idanwo l'o wa l'aye, Sugbọn eyi t'o buruju, K'a ma r'owo k'aisan de ni JAH jọwọ ma fi eyi se wa. AMIN

Hymn 108 – KERUBU ati Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia