Hymn 109 – K'A fi ope fun Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "K'A fi ope fun Oluwa" (C&S Hymn #109, Yoruba). 1. K'A fi ọpẹ fun Oluwa, Fun gbogbo ọpọ anu Rẹ, K'a wa di ihamọra wa,…
1. K'A fi ọpẹ fun Oluwa, Fun gbogbo ọpọ anu Rẹ, K'a wa di ihamọra wa, Lati b'esu jagun. Esu n'ipa sugbọn a o sẹgun, Ni agbara Mẹtalọkan, Ileri ti Oluwa sẹ, Y'o wa sibẹ titi. 2. Gbogbo ayé ẹ ho f'ayọ, Ki gbogbo wa si kun fun 'sẹ, Ki a ja titi de opin, K'a si fi 'da le'lẹ. Lẹsẹ Kristi Ọmọ Baba, Ni ibi awọn Angeli n yọ, K'a ba wọn yin Baba loke, Ọmọ, Ẹni lailai. 3. Awa ọmọ Ijọ Séráfù, A fi ogo fun Oluwa, T'o jẹ k'ẹmi tun ri ẹmi, Ogo f'orukọ Rẹ. Gb'oju s'oke wo asia, Fun gbogbo awọn t'o segun, Ẹyin ara ẹ ku abọ, Ki Baba pẹlu yin. 4. Awọn t'o ti sẹgun saaju, Wọn n wo wa bi awa ti n ja, Wọn si n fi ohun kan wi pé, Ara ma jafara. Nitor' akoko diẹ lo ku, Ti ayé yi yoo kọja lọ, Bi asẹgun a daju pe, A o gb'ade iye. 5. Awa si tun ki asaju wa, Ati awọn 'mọ ogun rẹ, Ara ẹ ku isẹ ẹmi, K'a gb'ọwọ lọwọ ara wa. Ẹ ku abọ ẹyin ku ile K'Ọlọrun pẹlu gbogbo wa, K'o si fi ade Ogo Rẹ, De gbogbo wa lori. 6. Ọpẹ ni fun Mẹtalọkan, T'o ba wa fọ 'tẹgun esu. Halleluyah s'Ọlọrun wa, Oju ti Lusifa. Ara ẹ jo pẹlu ayọ, Ara ẹ gbe ohun s'oke, Ki Baba fun wa ni 'fẹ Rẹ. Eyi ti ko l'ẹgbẹ. AMIN
Hymn 109 – K'A fi ope fun Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia