Hymn 107 – FI IYIN fun olus' aguntan Israeli | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "FI IYIN fun olus' aguntan Israeli" (C&S Hymn #107, Yoruba). 1. FI IYIN fun olus' aguntan Israeli, Ẹni ti o da Ijọ yi…
1. FI IYIN fun olus' aguntan Israeli, Ẹni ti o da Ijọ yi silẹ: Ẹ fi'yin fun Baba Mẹtalọkan Mimọ, Ẹni ti o fun wa ni isẹgun; Ẹ f'ogo f'Orukọ Jehovah Mimọ, Ẹ k'Alleluyah s'Ologo julọ, Ẹ fi duru kọrin mimọ si Ọba wa, Ẹni t'O mbẹ ninu imọlẹ nla. 2. Ẹ damuso ẹyin Ọm'Ẹgbẹ Séráfù, Ẹ bu s'ayọ, ẹ kọ orin mimọ S'Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, Ẹni t'O se Olurapada wa; Ẹ yin Jesu Kristi Olurapada, Ẹ ke Hosannah si Ọba wa, Ẹ fi duru kọrin mimọ si Ọba wa, Ẹni t'o mbẹ ninu agbara nla. 3. Ẹyin ẹgbẹ Akọrin Mimọ l'agbo yi, Ẹ mura lati kọ orin didun, S'Ọlọrun Ẹlẹda t'o mbe ninu Ogo; Mo mọ p'Ade Ogo yoo jẹ tiyin; Ẹyin agba lọkunrin, ẹ damure yin, Kristi Oluwa l'o ń pe yin si'sẹ Rẹ, Ẹyin agba l'obinrin, ẹ tubọ mura, Kristi Oluwa ki yoo fi yin silẹ. 4. Kristi, a bẹ Ọ loni, fun wa l'agbar' Ẹmi, K'awa k'o le se isẹ Rẹ dopin; Ran agbara 'mọlẹ si Ijọ Mimọ yii, Jẹ ki 'fẹ otitọ wa larin wa, Ba wa fọ 'tẹgun esu, ọta ẹmi wa, K'a le j'ẹni ajogun 'jọba Rẹ, Ẹ f'ayọ kọ orin mimọ si Ọba wa, Ẹni t'O mbẹ ninu Ogo didan. 5. Kristi to wa l'ọna gbogbo, ti awa n tọ, Mase jẹ k'a tele ogo asan, Eyi ti ise wura, fadaka at'asọ, Tọ wa, Olugbala s'ọna totọ, Mu wa k'ọna gbogbo t'esu silẹ, Ka le se ara wa titi dopin, Ẹ f'ayọ kọrin isẹgun s'Oluwa, Ẹni t'O mbẹ ninu Ọlanla Rẹ. 6. Ogo ni fun Baba, Ẹni Mimọ julọ; Ogo ni fun Mẹtalọkan Mimọ, Ogo ni fun Krist' Ọmọ Baba ayérayé, Ogo fun Ẹni Mimọ titi lai; Kristi Mimọ a bẹ Ọ, mu wa d'emi, Lati juba f'Orukọ Rẹ Mimọ; Ẹ fi duru kọrin Mimọ si Ọba wa, Ẹni t'o mbẹ ninu imọlẹ Nla. AMIN
Hymn 107 – FI IYIN fun olus' aguntan Israeli | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia