Hymn 106 – OLUWA, ye wa gba wa o Baba Ire | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA, ye wa gba wa o Baba Ire" (C&S Hymn #106, Yoruba). 1. OLUWA, ye wa gba wa o Baba Ire, A fi 'rẹlẹ sin O, Baba…
1. OLUWA, ye wa gba wa o Baba Ire, A fi 'rẹlẹ sin O, Baba Ire, A sọpẹ loni, A dupẹ (2ce) Fun Baba o, Baba ire 2. Baba ye wa wo wa o, Baba ire, A f'irẹlẹ sin Baba o, Baba ire, A m'ọpẹ a tun mu 'yin wa, (2ce) Fi isin Ọ o, Baba ire. 3. Fun wa l'emi ifẹ, Baba wa, Ka le f'ifẹ sin Ọ o, Baba wa, Jọwọ ye, fun wa ni ifẹ (2ce) Ka le yin Ọ, Baba ire. 4. K'ọmọ wa mase yanku o, Baba ire, Ka le dagba ka darugbo, Baba ire, A dupẹ, a tun t'ọpẹ da,(2ce) Fun Baba o, Baba ire. AMIN
Hymn 106 – OLUWA, ye wa gba wa o Baba Ire | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia