Hymn 095 – E JE ka jumo f'ope f'Olorun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E JE ka jumo f'ope f'Olorun" (C&S Hymn #095, Yoruba). 1. Ẹ JẸ ka jumọ f'ọpẹ f'Ọlọrun, Orin iyin, at'ọpẹ lo yẹ wa,…

Hymn 095 – E JE ka jumo f'ope f'Olorun | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹ JẸ ka jumọ f'ọpẹ f'Ọlọrun, Orin iyin, at'ọpẹ lo yẹ wa, Iyanu n'ifẹ Rẹ si gbogbo wa, Ẹ kọrin 'yin s'Ọba Olore wa. Halleluyah! Ogo ni fun Baba A f'ijo, ilu yin Ọlọrun wa, Alaye ni o yin Ọ bo ti yẹ, Halleluyah! Ogo ni fun Baba 2. Ki l'a fi san j'awọn t'iku ti pa? Iwọ lo f'ọwọ wọ wa di oni; 'Wọ lo n sọ wa to n gba wa lọw'ewu, Ẹ kọrin 'yin s'Olutọju wa. 3. Gbogbo alaye l'O n fun l'Ounjẹ wọn, Iwọ lo n pese f'onikaluku, Iwọ lo n sikẹ ẹda Rẹ gbogbo, Ẹ kọrin 'yin si Onibu-ọrẹ. 4. Ohun wa ko dun to lati kọrin, Ẹnu wa ko gboro to fun ọpẹ, B'awa n'ẹgbẹrun ahọn nikọkan, Wọn kere ju lati gb'ọla Rẹ ga. 5. Gbe wa leke 'soro l'ọjọ gbogbo, Fun wa l'ayọ at'alafia Rẹ, Jẹ k'ari 'bukun gba lọ'le wa, K'a ba le wa f'ogo f'orukọ Rẹ. 6. Ẹyin Angẹli l'ọrun wa ba wa gbe, Orin iyin at'ọpẹ l'o yẹ wa, S'Ọba wa aiku Ọlọla-julọ, Ọba wa Jehofa t'o j'Ọba. AMIN

Hymn 095 – E JE ka jumo f'ope f'Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia