Hymn 094 – JESU, mo wa sodo re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU, mo wa sodo re" (C&S Hymn #094, Yoruba). 1. JESU, mo wa sọdọ rẹ, Jẹ ki n le ma tọ Ọ lẹyin, Bi 'ni mi gbogbo…
1. JESU, mo wa sọdọ rẹ, Jẹ ki n le ma tọ Ọ lẹyin, Bi 'ni mi gbogbo segbe, Ti ero mi gbogbo si pin. Ẹ yin logo, ẹyin Mimọ, Ẹ f'ọpẹ fun Baba loke, Da wa si l'ẹgbẹ Séráfù, Ni 'kẹhin gba ọkan wa la. 2. Keferi, Imale, ẹ wa, Onigbagbọ, ma kalọ, K'a jọ yin Ọlọrun wa, K'a le d'ade ni 'kẹhin. 3. A dupẹ lọwọ Ọlọrun, T'o fi Jesu Kristi fun wa, Lati ra arayé pada, Lọwọ ẹsẹ at'esu. 4. Ẹgbe Séráfù damure, Ẹgbe Kérúbù kun f'adura, Olugbala yoo gba wa la, Oluwosan yoo wo wa san. 5. Ọjọ mbọ t'ayé yoo pin, Ẹ sọra ẹyin Mimọ; K'ẹni ‘waju tẹ siwaju, K'ẹni ẹhin ma jafara. 6. Awọn to sẹgun saju, Wọn n wo wa b'a ti n yọ loni, Wọn nkan sara si wa wi pé, Tẹ siwaju, ma fa s'ẹyin. 7. Ma siyemeji lọna yii, B'o ti wu k'o le fun ọ to; Séráfù mase foya, Adun y'o kẹhin ayé rẹ. 8. Nigba ti 'pe kẹhin ba dun, Jesu y'o ko wa de Kenaani, Jẹ ka l'ayọ lọdọ Rẹ, Fi wa s'agbala itura. 9. Ẹ f'ogo fun Baba loke, Ẹ f'ogo fun Ọmọ pẹlu; Ẹ f'ogo fun Ẹmi Mimọ, Mẹtalọkan lọpẹ yẹ fun. Ẹ yin logo, ẹyin Mimọ, Ẹ f'ọpẹ fun Baba loke, Da wa si n'Ijọ Séráfù, Ni 'kẹhin gba ọkan wa la. AMIN
Hymn 094 – JESU, mo wa sodo re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia