Hymn 926 – BABA orun, 'wo lo mu wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "BABA orun, 'wo lo mu wa" (C&S Hymn #926, Yoruba). 1. BABA orun, 'wo lo mu wa D'ojo oni l‘alafia Pele I’O nto isise wa…
1. BABA orun, 'wo lo mu wa D'ojo oni l‘alafia Pele I’O nto isise wa T’O si nf'iso Re so wa ‘Wo Ore at’Amona wa A fe fi ope fun O Ao se le yin O b'o ti ye Fun ‘fe Re ti ki pada? 2. Ni gbogbo igba t’o koja L’a nri anu gba lotun Itoju on iseun-ife Ko fi igba kan jin na Ife ati aba orun Mba wa gbe tosan-toru Ibukun t’a ko le siro Ntan imole s’ona wa. 3. N’nu ‘danwo nla l’a ti koja Iji ‘ponju ti lu wa Idamu ti sokun bo wa Tobe t’a ko fi ri O Sibe ife Re ko ko wa Sibe n’nu banuje wa Iranwo t’a nse f’ara wa Nipa agbara Re ni. 4. Opo awon olufe wa Ti de opin ajo won Ara, omo ati ore Nwona lati pade wa Nigbat’ ajo wa ba pari Ti a si se alaisi Baba, mu wa la okun ja Sinu mole ailopin. Amin
Hymn 926 – BABA orun, 'wo lo mu wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia