Hymn 092 – OKAN mi yin Oba orun | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OKAN mi yin Oba orun" (C&S Hymn #092, Yoruba). 1. ỌKAN mi yin Ọba ọrun, Mu ọrẹ wa sọdọ Rẹ; 'Wọ ta wosan, ta dariji,…

Hymn 092 – OKAN mi yin Oba orun | C&S Yoruba Hymnary
1. ỌKAN mi yin Ọba ọrun, Mu ọrẹ wa sọdọ Rẹ; 'Wọ ta wosan, ta dariji, Tal'a ba ha yin ni Rẹ? Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Yin Ọba Ainipẹkun )2ce 2. Yin fun ọkọ 'gbala 'kẹhin, To sọkalẹ f'arayé; O si yan Bab' Aladura, Lati jẹ Alakoso; Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Yin Ọba Ainipẹkun )2ce 3. Yin fun anu to ti fihan, Lori Ẹgbẹ Séráfù; To pa wa mọ titi d'oni, To si fun wa n'isẹgun. Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Ologo n'nu otitọ )2ce 4. Yin fun abo ti o daju, To n fun wa lojurere; Ninu wahala oun 'danwo, Anu Rẹ wa bakan naa, Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Ologo Olotitọ )2ce 5. Yin fun abo ti o daju, Ta n ri n'Ijọ Séráfù Ajẹ, Oso, oun Sanpọnna, Wọn ko ri wa gbese mọ, Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Ọba Alainipẹkun )2ce 6. A n gba b'itana eweko, T'afẹfẹ n fẹ, t'o si n rọ; 'Gba ti a n wa, ti a si n ku, Ọlọrun wa bakan naa. Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Yin Ọba Alainipẹkun )2ce 7. Bi baba ni o n tọju wa, O si mọ ailera wa; Jẹjẹ lo n gbe wa l'apa Rẹ, O ń f'ounjẹ iye bọ wa. Yin Oluwa, Yin Oluwa, ) Anu Rẹ yi ayé ka )2ce 8. Ogun ọrun, ẹ ba wa yin, Baba, Ọmọ, oun Ẹmi; Orun, osupa, ẹ wolẹ, Ati gbogbo agbayé. Ẹ ba wa yin, ẹ ba wa yin) Ọlọrun Mẹtalọkan )2ce AMIN

Hymn 092 – OKAN mi yin Oba orun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia