Hymn 91 – E DAMURE eyin Seraf | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "E DAMURE eyin Seraf" (C&S Hymn #91, Yoruba). 1. Ẹ DAMURE ẹyin Seraf' Ẹ mu harpu yin pẹlu; Ẹ jẹ ki Kimbali yin dun,…

Hymn 91 – E DAMURE eyin Seraf | C&S Yoruba Hymnary
1. Ẹ DAMURE ẹyin Seraf' Ẹ mu harpu yin pẹlu; Ẹ jẹ ki Kimbali yin dun, Lati pade Ọba wa. Loke odo ọna Eden Ibugbe mimọ to dara, Nibi Kérúbù, Séráfù, Yin Baba Mimọ logo. 2. Fi 'lu ati 'jo yin Baba, Baba y'o f'ayọ fun wa; Bi awa ba jẹ le gbagbọ, Ere pupọ ni fun wa. 3. Baba masai fi 're fun wa, Awa Seraf' ayé yi; Se wa yẹ fun isin gbogbo, Ka gb' ade wa nikẹhin. 4. Baba to gbọ ti Elijah, Masai gbọ ti Séráfù; Jehovah-Jire Ọba wa, Se wa yẹ lọjọ 'kẹhin. 5. A o f'ogo fun Baba wa, Fun Ọmọ to da wa si; Bi ọdun si ti n yipo lọ, Mẹtalọkan la o yin. AMIN

Hymn 91 – E DAMURE eyin Seraf | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia