Hymn 918 – OGO, iyin, ola | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OGO, iyin, ola" (C&S Hymn #918, Yoruba). 1. OGO, iyin, ola Fun Olugbala wa T’o da eni wa si Titi d'ojo oni Ayo kun…
1. OGO, iyin, ola Fun Olugbala wa T’o da eni wa si Titi d'ojo oni Ayo kun okan wa Fun anfani nla yi Lati sise fun O N’nu ogba re laye. 2. A dupe fun toni On agbara t'erni At’ebun ife nla Ti o fi so wa po Olusagutan wa Tewo gba iyin wa Nitori anu Re Se wa l’okan laelae. 3. Bukun wa, Oluwa Loni ajodun wa Ran ami Re si wa K’a layo n'nu sin Re Ka si s'aseyori N’nu ise isin wa K’a si fi Jesu se Igbekele wa lae. 4. Eleda, Oluwa Orisun gbala wa Se wa ye f’ajodun Ti ibugbe loke N‘ipari ajo wa N’nu aye osi yi K'a le ni ibugbe Lodo Re Oluwa. Amin
Hymn 918 – OGO, iyin, ola | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia