Hymn 915 – OLUWA, a gbe okan wa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA, a gbe okan wa" (C&S Hymn #915, Yoruba). 1. OLUWA, a gbe okan wa Si O n‘nu orin iyin A m’ore ope wa fun O Pelu…

Hymn 915 – OLUWA, a gbe okan wa | C&S Yoruba Hymnary
1. OLUWA, a gbe okan wa Si O n‘nu orin iyin A m’ore ope wa fun O Pelu iho ayo nla Gbogbo papa f'ewa bora Awon oke nho f‘ayo Oka po l’afonifoji Tobe ti won fi nkorin. 2. Loni, ojo ikore wa Awa jewo ore Re Awa f’ope mu ebun wa Akoso ibukun Re Wo l’o nfi ore-ofe bo Okan awa eda Re Wo ti npese onje ojo Fi onje orun bo wa. 3. A nfarada oru ojo Laalaa a si ma su-ni Sugbon nigbati oorun wo Simi de fun alaare Se wa l’eni itwogba Gbat‘ angeli ba nkore K’a je alikama Kristi Ti On y‘o to si aba. 4. lbukun n'ile Olorun Bit‘ awon mimo wa lae Papa wura teju ni be Odo re ndan bi Kristal Orin egbe mimo t'ohun Dapo mo tiwa loni Bukun orin kore na po Ti a o ma ko titi. Amin

Hymn 915 – OLUWA, a gbe okan wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia