Hymn 907 – AH! ojo iyanu ojo ’yanu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AH! ojo iyanu ojo ’yanu" (C&S Hymn #907, Yoruba). 1. AH! ojo iyanu ojo ’yanu Ojo ti n ko le gbagbe Gba mo sako lo ninu…
1. AH! ojo iyanu ojo ’yanu Ojo ti n ko le gbagbe Gba mo sako lo ninu okunkun Ni mo ba Jesu pade Ore olufe, Eni ikaanu B'okan aini mi pade O mu beru lo, pel'ayo ni mo n rohin O mu ghogb' okunkun lo! Egbe: Ogo orun si kun ‘nu okan mi Gba t’Olugbala so mi di pipe A we ese mi nu, ale mi si d'owuro Ogo orun si kun 'nu okan mi. 2. A bi mi nipa Emi pelu ye Sinu ebi Olorun A da mi lare nipa 'fe Kristi Mo ni‘gbekele t’o ga Ise naa di sise logan nigba Ti mo wa bi elese Mo gba ebun oor-ofe eyi t’O mu wa O gba mi, yin Ooko Re. Egbe: Ogo orun si kun ‘nu... 3. Nisin yi mo n’ireti t’o wa lae Lehin opin ajo mi O daju pe mo n’ireti l’orun N’ile ologo julo Ati nitori ojo yanu ni Ti mo wole l'ese Re Oro ainipekun ibukun l’atorun Ti mo gba ni owo Re. Egbe: Ogo orun si kun ‘nu okan mi Gba t’Olugbala so mi di pipe A we ese mi nu, ale mi si d'owuro Ogo orun si kun 'nu okan mi. Amin
Hymn 907 – AH! ojo iyanu ojo ’yanu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia