Hymn xl – Baba a tun pade l'oruko Jesu | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "Baba a tun pade l'oruko Jesu" (C&S Hymn #xl, Yoruba). Baba a tun pade l'orukọ Jesu, A si wa tẹriba l'abẹ ẹsẹ Rẹ, A tun…

Hymn xl – Baba a tun pade l'oruko Jesu | C&S Yoruba Hymnary
Baba a tun pade l'orukọ Jesu, A si wa tẹriba l'abẹ ẹsẹ Rẹ, A tun wa gb'ohun wa soke si Ọ, Lati wa aanu lati kọrin iyin. O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju, Sugbọn kikan kikan ni o si n pe, Njẹ a de a pada wa'le Baba. A sako b'aguntan ti ko l'olusọ, A ti nu b'aja ti ko gbohun ọdẹ, A ti sina kuro l'ọdọ Rẹ Baba, Dariji wa Baba si fa wa mọra. O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju, Sugbọn kikan kikan ni o si n pe, Njẹ a de a pada wa'le Baba. SOLO: Njẹ a de a pada wale Baba o ) FULL: Njẹ a de a pada wale Baba, )2ce SOLO: K'awọn aboyun wa ma bi wẹrẹ, FULL: Njẹ a de a pada wale Baba. SOLO: K'awọn agan ko tọwọ ala B'osun, O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju, Sugbọn kikan kikan ni o si n pe, Njẹ a de a pada wa'le Baba. FULL: Njẹ a de a pada wale Baba. SOLO: K'ọmọ wa ye ka ma gbe wọn gbin mọ, EGBE: Njẹ a de a pada wale Baba. O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju, Sugbọn kikan kikan ni o si n pe, Njẹ a de a pada wa'le Baba. ASẸ O se a ko yẹ fun ifẹ nla Rẹ, A sako kuro l'ọdọ Rẹ pọ ju, Sugbọn kikan kikan ni o si n pe, Njẹ a de a pada wa'le Baba.

Hymn xl – Baba a tun pade l'oruko Jesu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia