Hymn 893 – N'bere odun yi, odun titun yi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "N'bere odun yi, odun titun yi" (C&S Hymn #893, Yoruba). 1. N'bere odun yi, odun titun yi Oro itunu de, ti nle eru lo…
1. N'bere odun yi, odun titun yi Oro itunu de, ti nle eru lo Ohun keje jeje, ti Baba orun Ododo l’oro na, ti nm'okan wa yo. Egbe: E ma tesiwaju, omo imole Oro Re ko le ye, O nduro titi. 2. Ma beru ‘loro na, Mo wa pelu yin Emi n’iranwo yin at’agbara yin Emi y'o di yin mu, li owo ‘tun mi Mo pe yin, mo yan yin, lati je temi titi. Egbe: E ma tesiwaju.. 3. Fun opo odun ti mbe niwaju wa Opo ni ipese t'awon seleri lpese f‘alaini f'awon elese F'awn t'a npon loju, fun alailera wa. Egbe: E ma tesiwaju.. 4. Ko je fi wa sile, ko si ni ko wa Majemu Re daju ti ko le ye Iae A ro mo ‘leri yi, eru ko ba wa Olorun wa ti to, fun odun ti mbo. Egbe: E ma tesiwaju, omo imole Oro Re ko le ye, O nduro titi. Amin
Hymn 893 – N'bere odun yi, odun titun yi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia