Hymn 888 – IJO ti nduro pe | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IJO ti nduro pe" (C&S Hymn #888, Yoruba). 1. IJO ti nduro pe Lati ri Oluwa O si wa bakan na sibe Ko s‘alabaro fun Odun…

Hymn 888 – IJO ti nduro pe | C&S Yoruba Hymnary
1. IJO ti nduro pe Lati ri Oluwa O si wa bakan na sibe Ko s‘alabaro fun Odun nyi lu odun Ojo ngori ojo Sibe lairi Oluwa re O wa ninu ofo Ma bo, Jesu ma bo! 2. Awon mimo l‘aiye Opo won l‘oti ku Bi won si ti nlo l’okankan L’a te won gbe ‘ra won A te won lati sun Ki se ainireti A te won lati r'eju ni K'ile ogo to mo Ma bo, Jesu mabo! 3. Awon ola npo si Abgara esu nga Ogun ngbona, igbagbo nku lfe si di tutu Y’o ti pe to Baba Oloto Olore Wo ki y’o koya omije At’eje Ijo Re Ma bo Jesu ma bo! 4. A nfe gbo ohun Re A nfe f'oju kan O K‘a le gba ade at' ogo B‘a ti ngha ore Re Jo, wa m‘ese kuro A t‘egun at'eri K‘o si so aye osi yi D‘aye rere Tire Ma bo, Jesu ma bo. Amin

Hymn 888 – IJO ti nduro pe | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia