Hymn xix – Baba, Baba, awa wole niwaju Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Baba, Baba, awa wole niwaju Re" (C&S Hymn #xix, Yoruba). Baba, Baba, awa wolẹ niwaju Rẹ, Baba, Baba, tan'mọlẹ Rẹ si…
Baba, Baba, awa wolẹ niwaju Rẹ, Baba, Baba, tan'mọlẹ Rẹ si wa, Baba, Baba, oungbẹ Rẹ n gbẹ ọkan wa Ẹmi ọrun sọkalẹ sarin wa. Fun wa l'agbara At'ayọ n'nu ẹmi wa Ka le dabi awọn t'ase logo Ti n fi harpu wura yin i niwaju Rẹ, Pẹlu Stephen ni aya Abraham. A n wo iro ẹjẹ Rẹ n san kọjá lọ, Bi itanna wura ta se logo Isun iwẹnumọ fun 'fiji, ẹsẹ. Ti n san niha Jesu Olugbala. Fun wa l'agbara At'ayọ n'nu ẹmi wa Ka le dabi awọn t'ase logo Ti n fi harpu wura yin i niwaju Rẹ, Pẹlu Stephen ni aya Abraham. Ẹmi ọrun itansan 'mọle otitọ, Tansan 'bukun lati ila orun, Tan saarin wa bi t'ọjọ Pentikọsti, Jẹ ki ami Rẹ han siwaju wa. Fun wa l'agbara At'ayọ n'nu ẹmi wa Ka le dabi awọn t'ase logo Ti n fi harpu wura yin i niwaju Rẹ, Pẹlu Stephen ni aya Abraham.
Hymn xix – Baba, Baba, awa wole niwaju Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia