Hymn 877 – GBO orin 'yin dida aye | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "GBO orin 'yin dida aye" (C&S Hymn #877, Yoruba). 1. GBO orin 'yin dida aye T’egberun orile nko Orin didun bi t'angeli…

Hymn 877 – GBO orin 'yin dida aye | C&S Yoruba Hymnary
1. GBO orin 'yin dida aye T’egberun orile nko Orin didun bi t'angeli O ndun bi omi pupo 'Bukun, ogo, ipa gbala Fun Olorun lor‘ite Baba, Omo, Emi Mimo Olola, lainipekun. 2. Titi lo, lat‘oro d‘ale Lor‘olukuluku ‘le Lat‘ opolopo eniyan llu alawo pupa ‘Lawo dudu t'a da n’ide Funfun ti o po niye Omnira alarinkiri De ‘le awon Arabu. 3. Lati ebute otutu De ile ti o mooru Awon olokan gbigbona Leba okun Pasifik’ Lat’opo aimoye okan Onigbagbo alayo Awon to nsona bibo Re Won fere de Sion na. 4. Akojo orile-ede Lat’inu eya ahon Gbo, won nkorin iyin titi Gbo orin ologo ni O b’afonifoji mole O si ndun lori oke O ndun si waju tit‘o fi Kun ibugbe Olorun. 5. Gbo, didun orin na dapo Mo orin awon t’orun, Awon t’o koja n‘nu danwo Sinu isimi loke Won wo aso ailabawon Imo ‘segun lowo won Won nfi duru ko Hosana. 6. “Ogo fun Eni t'o fe wa T'O we wa n'nu eje Re K'oba, alufa, ma korin Si Baba, Olorun wa K'eeyan mimo on Angeli Ko Aleluya titi: Asegun orun apadi: Olodumare joba." Amin

Hymn 877 – GBO orin 'yin dida aye | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia