Hymn 811 – Tal' awon wonyi b'irawo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "Tal' awon wonyi b'irawo" (C&S Hymn #811, Yoruba). Tal' awọn wọnyi b'irawọ, Niwaju itẹ Mimọ, Ti wọn si de ade wura,…
Tal' awọn wọnyi b'irawọ, Niwaju itẹ Mimọ, Ti wọn si de ade wura, Ẹgbẹ ogo wo l'eyi? Gbọ! Wọn n kọ Halleluyah, Orin iyin Ọba wọn! Tani awọn ti n kọ mana, T'a wọ l'asọ ododo? Awọn ti asọ funfun wọn, Y'o ma funfun titi lai, Bẹni ki y'o gbo lailai, Nibo l'ẹgbẹ yi ti wa? Awọn wọnyi l'o ti jagun, F'ọla Olugbala wọn; Wọn jijakadi tit' iku, Wọn ki b'ẹlẹsẹ k'ẹgbẹ; Wọnyi ni ko s‘ sa f'ogun, Wọn sẹgun nipa Kristi. Wọnyi l'ọkan wọn ti gbọgbẹ Ninu 'danwo kikoro; Wọnyi ni o ti f'adura, Mu Ọlọrun gbọ ti wọn; Nisinsinyi wọn sẹgun, Ọlọrun re wọn lẹkun. Awọn wọnyi l'o ti sọra, Ti wọn fi 'fẹ wọn fun Krist' Wọn si y'ara wọn si mimọ, Lati sin nigba gbogbo, Nisinsin yii ni ọrun, Wọn wa l'ayọ l'ọdọ Rẹ. AMIN
Hymn 811 – Tal' awon wonyi b'irawo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia