Hymn 798 – EYIN ero nibo l'e n lo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EYIN ero nibo l'e n lo" (C&S Hymn #798, Yoruba). ẸYIN ero nibo l'ẹ n lọ, T'ẹyin ti‘mọ ‘pẹ, lọwọ yin? Awa n lọ pade Ọba…
ẸYIN ero nibo l'ẹ n lọ, T'ẹyin ti‘mọ ‘pẹ, lọwọ yin? Awa n lọ pade Ọba wa, Gẹgẹ bi 'leri Rẹ si wa. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Ẹyin ero, ẹ sọ fun wa, T'ayọ pipe ti mbẹ nibẹ; T'asọ ala at'ade Ogo, Ti Jesu y'o fun wa loke. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. A ko ni 'bugbe kan niyin, O buru bi'hin jẹ'le wa; Ayọ l'oorọ, ẹkun lalẹ; Sugbọn eyi ko si loke. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Ẹgbẹ ọrun, ẹ silẹkun, F'ẹgbẹ ayé lati wọle; Awa n'isẹ at'ipọnju, Wọn de lati b'Oluwa gbe. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Ogunlọgọ nibi gbogbo, Ti wọn ti sẹgun ayé yi, Ọlọrun sọ wọn di ọmọ, Wa ọrẹ mi, ki ilẹ to su. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Ọja ayé, ọja asan, B'Oluwa n'ọja, k'o jere, Ọrẹ ayé, ọrẹ asan, B'Oluwa s'ọrẹ, ki idani. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Wo! ko tun s'adun layé mọ, Ibajẹ pọ ju rere lọ; B'Oluwa rẹ, pinnu loni, Ki 'gbẹyin rẹ ba le layọ. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. Agbagba mẹrinlelogun, Ẹyin l'awa fẹ ba k'ẹgbẹ, 'Tori ko s'adun layé mọ, Ẹ ka wa yẹ f'adun loke.. A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai. AMIN A n lọ s'afin, s'afin Ọba rere, A n lọ s'ilẹ 'leri, nibi ti ẹsẹ ko le de, Nibi ti 'sinmi wa lailai.
Hymn 798 – EYIN ero nibo l'e n lo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia