Hymn 797 – EMI at'ara ile mi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "EMI at'ara ile mi" (C&S Hymn #797, Yoruba). EMI at'ara ile mi, Yoo ma sin Oluwa wa; Sugbọn emi papa; Yoo f'iwa at'ọrọ…
EMI at'ara ile mi, Yoo ma sin Oluwa wa; Sugbọn emi papa; Yoo f'iwa at'ọrọ han, Pe mo mọ Oluwa t'ọrun, Mo n fi ọkan totọ sin. Em'o f'apẹrẹ 're le'lẹ; N ó mu idena na kuro; Lọdọ ọm'ọdọ mi; N ó f'isẹ wọn han n'iwa mi Sibẹ n'nu 'sẹ mi ki n si ni Ọla na ti ifẹ. Emi ki y'o soro gb'ipẹ, Emi ki y'o pẹ tu ninu, Ọm' ẹhin Ọlọrun; Mo si fẹ jẹ ẹni mimọ; Ki n si fa gbogbo ile mi, S'oju ọna ọrun Jesu, b'O ba de'na 'fẹ na, Ohun elo t'Iwọ fẹ lo, Gba s'ọwọ ara Rẹ! Sisẹ ifẹ rere n'nu mi, Ki n fi b'onigbagbọ totọ, Ti ń gbe l'ayé han wọn Fun mi l'ore-ọfẹ totọ, Njẹ! Emi de lati jẹri, 'Yanu orukọ Rẹ, Ti o gba mi l'ọwọ egbe; Ire eyi t'a mọ l'ọkan, Ti gbogb' ahọn le sọ. Emi t'o bọ lọwọ ẹsẹ, Mo wa lati gba'le mi la, Ki n wasu 'dariji; F'ọmọ, f'aya, f'ọmọ-dọ mi Lati mu wọn tọ'na rere, Lọ si ọrun mimọ. AMIN
Hymn 797 – EMI at'ara ile mi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia