Hymn 763 – NIHIN l'awa n je 'rora | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "NIHIN l'awa n je 'rora" (C&S Hymn #763, Yoruba). NIHIN l'awa n jẹ 'rora, Nihin ni a ma pinya, L'ọrun, ko si 'pinya. A!…

Hymn 763 – NIHIN l'awa n je 'rora | C&S Yoruba Hymnary
NIHIN l'awa n jẹ 'rora, Nihin ni a ma pinya, L'ọrun, ko si 'pinya. A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. Awọn t'o fẹran Jesu, Wọn o lọ s'oke ọrun, Lọ b'awọn t'o ti lọ. A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. Ọmọde y'o wa nibẹ, T'o wa Ọlọrun l'ayé, Ni gbogbo 'le ẹkọ, A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. Olukọ, baba, iya, Wọn a pade nibẹ na, Wọn ki o pinya mọ. A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. Bi a o ti yọ pọ to! Gba t'a ba r'Olugbala, Ni ori itẹ Rẹ! A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. Nibẹ l'a o kọrin ayọ, Titi ayé ailopin; L'a o ma yin Jesu, A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ. AMIN A! bi o ti dun to! Dun to, dun to , dun to! A! bi o ti dun to, Gba t'a ki o pinya mọ.

Hymn 763 – NIHIN l'awa n je 'rora | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia