Hymn 762 – IBUKUN ni f'oku | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IBUKUN ni f'oku" (C&S Hymn #762, Yoruba). IBUKUN ni f'oku, T'o sinmi le Jesu; Awọn t'o gb'ori wọn, Le okan aya Rẹ.…
IBUKUN ni f'oku, T'o sinmi le Jesu; Awọn t'o gb'ori wọn, Le okan aya Rẹ. Iran 'bukun l'eyi, Ko si 'boju larin; Wọn ri Ẹn'Imọlẹ, Ti wọn ti fẹ lati ri. Wọn bọ lọwọ ayé, Pẹlu aniyan rẹ; Wọn bọ lọwọ ewu, T'o n rin l'ọsan, l'oru. Lori iboji wọn, L'awa n sọkun loni, Wọn j'ẹn' ire fun wa, T'a ki y'o gbagbe lai. A k' y'o gbohun wọn mọ, Ohun ifẹ didun; Lat‘ oni lọ, ayé Ki o tun mọ wọn mọ. Ẹyin oninure, Ẹ fi wa silẹ lọ; A o sọkun yin titi, Jesu pa sọkun ri. Sugbọn a fẹ gbohun, Olodumare na; Y'o ko, y'o si wi pé, Ẹ dide, ẹ si yọ. AMIN
Hymn 762 – IBUKUN ni f'oku | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia