Hymn 748 – WI jade larin keferi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "WI jade larin keferi" (C&S Hymn #748, Yoruba). WI jade larin keferi, 'Oluwa l'Ọba, Wi jade! Wi jade! Wi jade…
WI jade larin keferi, 'Oluwa l'Ọba, Wi jade! Wi jade! Wi jade f'orilẹ-ede, mu ki wọn kọrin, Wi jade! Wi jade! Wi jade tiyin tiyin pe Oun o ma pọ si, Pe, Ọba nla Ologo l'Ọba alafia; Wi jade tayọ tayọ bi iji tilẹ n ja; Pe O joko lor' isan omi, Ọba wa titi lai. Wi jade larin keferi pe, Jesu n jọba, Wi jade! Wi jade! Wi jade f'orilẹ-ede, mu k'ide wọn ja, Wi jade! Wi jade Wi jade fun awọn ti n sokun pe Jesu ye; Wi jade f'alarẹ pe, Oun n funni n'isinmi; Wi jade f'ẹlẹsẹ pe, O wa lati gbala; Wi jade fun awọn ti n ku pe, O ti segun iku. Wi jade larin keferi, Krist' n jọba l'oke, Wi jade! Wi jade! Wi jade fun keferi, Ifẹ n'ijọba Rẹ, Wi jade! Wi jade! Wi jade lọna opopo l'abuja ọna, Jẹ ko dun jakejado ni gbogbo agbayé; B'iro omi pupọ ni k'iho ayọ wa jẹ, Titi gbohun-gbohun y'o fi gbe iro naa de 'kangun ayé. AMIN
Hymn 748 – WI jade larin keferi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia