Hymn 747 – IRANSE Olorun, e ma kede Re | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "IRANSE Olorun, e ma kede Re" (C&S Hymn #747, Yoruba). 'RANSẸ Ọlọrun, ẹ ma kede Rẹ, Ẹ ma k'okiki Jesu asẹgun ga; Ijọba…
'RANSẸ Ọlọrun, ẹ ma kede Rẹ, Ẹ ma k'okiki Jesu asẹgun ga; Ijọba Rẹ l'ogo lor' ohun gbogbo. Olodumare, O n jọba loke, O si sunmọ wa, O mbẹ lọdọ wa; Ijọ nla ni y'o kọrin isẹgun Re; O n jẹwọ pe, ti Jesu ni igbala. Igbala ni t'Ọlọrun t'o gunwa! Gbogb' ayé kigbe, ẹ f'ọla f'Ọmọ, Iyin Jesu nigba gbogbo Angel n ke, N'idoju bo‘lẹ, wọn n sin Ọd'aguntan Ẹ jẹ k'awa sin, k'a f'iyin Rẹ fun, Ogo, agbara, ọgbọn at'ipa, Ọla at'ibukun, pẹl'awọn Angẹli, Ọpẹ ti ko lopin at'ifẹ titi. AMIN
Hymn 747 – IRANSE Olorun, e ma kede Re | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia