Hymn 740 – IRAWO wo l'eyi | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "IRAWO wo l'eyi" (C&S Hymn #740, Yoruba). IRAWỌ wo l'eyi? Wo b'o ti dara to, Amọna awọn Keferi, S'ọdọ Ọba ogo. Wo awọn…

Hymn 740 – IRAWO wo l'eyi | C&S Yoruba Hymnary
IRAWỌ wo l'eyi? Wo b'o ti dara to, Amọna awọn Keferi, S'ọdọ Ọba ogo. Wo awọn amoye, Ti ila orun wa, Wọn wa fi ori balẹ fun, Jesu Olubukun. Imọlẹ ti Ẹmi, Ma sai tan n'ilu wa; Fi ọna han wa, ka le tọ, Emmanueli wa. Gbogbo iru-malẹ, Ati igba-malẹ, Ti a mbọ n'ilẹ Keferi, K'o yago fun Jesu. Ki gbogbo abọrẹ, Ti mbẹ ni Afrika, Jẹ amoye ni otitọ, Ki wọn gb'ẹbọ Jesu. Baba, Ẹlẹda wa, Ti o fi Jesu han, Awọn Keferi igbani; Fi han fun wa pẹlu. AMIN

Hymn 740 – IRAWO wo l'eyi | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia