Hymn 739 – HA! Kerubu, e se giri | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "HA! Kerubu, e se giri" (C&S Hymn #739, Yoruba). HA! Kérúbù, ẹ se giri, Ẹ ma jafara, Esu n gbogun l'ọsan, l'oru, O n se…
HA! Kérúbù, ẹ se giri, Ẹ ma jafara, Esu n gbogun l'ọsan, l'oru, O n se lasan ni. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. Ha! Séráfù, ẹ se giri, Ẹ ma sọ'ra nu, Ẹ ma f'aye silẹ f'esu, N'ijakadi yin. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. Ẹyin Ẹgbẹ Aladura, Ninu Ẹgbẹ yi; K'Ọlọrun Olodumare, Ma jẹ k'o rẹ yin. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. Ẹyin Ọm'Ẹgbẹ Akọrin, Ẹ t'ohun yin se, A o kọrin Halleluyah, Pẹl' awọn t'ọrun. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. Gbogbo Ẹgbẹ, ẹ ho, ẹ yọ, Ẹ tẹsiwaju, A o sẹgun gbogbo ọta, Ni orukọ Rẹ Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. Ogo ni fun Baba loke, Ogo ni f'Ọmọ, Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Lai ati lailai. Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ. AMIN Kérúbù ati Séráfù, Ẹ damure yin, Ka le doju 'ja kọ esu, Ati ogun rẹ.
Hymn 739 – HA! Kerubu, e se giri | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia