Hymn 729 – E DIDE omo ogun gbala | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "E DIDE omo ogun gbala" (C&S Hymn #729, Yoruba). Ẹ DIDE ọmọ ogun gbala, Gbe orukọ Jesu ga, Fun ọjọ nla t'a ri loni, Ti…
Ẹ DIDE ọmọ ogun gbala, Gbe orukọ Jesu ga, Fun ọjọ nla t'a ri loni, Ti Maikieli Balogun wa. Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. A dupẹ pe o jẹ tiwa, Larin Ẹgbẹ Séráfù, Ko si b'esu tilẹ gb'ogun, Maikiel a bori wọn. Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. L'ọjọ na t'ogun gb'ọrun kan Ọrun, ayé wariri, Ibẹru nla l'o gb'ayé kan, Maikiel f'ọkọ rẹ g'esu Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. Mo gb'ohun na lati ọrun wa Pe egbe ni fun ayé, A le olufisun s'ayé, Awọn ayanfẹ yoo la Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. Ẹgbẹ Kérúbù ma bẹru, Pe Maikieli jẹ tiwa, Oso, ajẹ ko n'ipa mọ, Lori Ẹgbẹ Mimọ yi. Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. Jesu, Ọmọ Mimọ Baba, A f'ogo f'Orukọ Rẹ, Pe Maikiel ti sẹgun esu, Awọn ogun esu fọ. Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. 'Gba ti 'pe 'kẹhin ba si dun, Ọlọrun awa mbẹ Ọ, Ma jẹ k'ọwọ esu tẹ wa, K'a si le gb'ade iye. Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa. AMIN Maikieli Mimọ Balogun Maikieli Mimọ Balogun, S'amọna Ẹgbẹ wa d'opin B'awa sẹgun Lusifa.
Hymn 729 – E DIDE omo ogun gbala | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia