Hymn 728 – AJE n se lasan ni Kerubu a pa won run | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AJE n se lasan ni Kerubu a pa won run" (C&S Hymn #728, Yoruba). AJẸ n se lasan ni Kérúbù a pa wọn run; Ọba awọn Ọba,…
AJẸ n se lasan ni Kérúbù a pa wọn run; Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Sanpọnna n se lasan ni, Maikeli a sori fun. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Babalawo n se lasan ni, Séráfù a pa wọn run. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Igunnu n se lasan ni, Kérúbù a pa wọn run. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Egungun n se lasan ni, Kérúbù a pa wọn run Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Ẹyin asaju wa, Ẹ foriti ka le gbade. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Baba Aladura ko Le ko wa de'lẹ Kanaan. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Ọlọrun Mẹtalọkan oun ni Ọlọrun Séráfù. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Nigba ti a ba si d'ọrun, A o kọrin Halleluyah. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. Ẹ ba wa k'aleluya Halle Halle Haleluya. Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo. AMIN Ọba awọn Ọba, Ọlọrun ayérayé, Ọba ogo.
Hymn 728 – AJE n se lasan ni Kerubu a pa won run | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia