Hymn 716 – KERUBU pelu Serafu | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "KERUBU pelu Serafu" (C&S Hymn #716, Yoruba). KÉRÚBÙ pẹlu Séráfù, A ki yin fun ajọdun oni, Aladura l'o pejọpọ, Lati…
KÉRÚBÙ pẹlu Séráfù, A ki yin fun ajọdun oni, Aladura l'o pejọpọ, Lati f'Ogo fun Baba loke. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. A dupẹ lọwọ Ọlọrun T'o da wa si d'ajọdun oni, Lati f'Ogo Ọlọrun han, L'akoko t'ọta fẹ kẹgan wa. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. Ọlọrun Olodumare, Iwọ ni 'yin at'ọpẹ yẹ fun, Iwọ l'o ni k'eweko hu, O si ri bẹ nipa asẹ Rẹ. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. Iwọ l'o wi pé k'okun wa, O si ri bẹ nipa asẹ Rẹ, Iwọ l'o wi pé k'ọsan wa, O si ri bẹ nipa asẹ Rẹ. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. Ọlọrun t'o gbọ ti Mose, T'ọmọ arayé ko r'idi rẹ, Ọlọrun t'o gbọ t'Elijah, A gbọ tiwa 'nu ajọdun oni. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. Ọlọrun Baba Olore, A dupẹ fun ajọdun oni yi, Asẹ l'o fi da imọlẹ, Jehovah Jire pese fun mi, Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. Ẹ f'Ogo fun Baba loke, Ẹ f'Ogo fun Ọmọ loke, Ẹ f'Ogo fun Ẹmi Mimọ, Mẹtalọkan ni ọpẹ yẹ fun. Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù. AMIN Ho f'ayọ, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Séráfù, Ho f'Ogo, ho f'ayọ, Ho f'ayọ, ẹyin Ijọ Kérúbù.
Hymn 716 – KERUBU pelu Serafu | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia