Hymn 715 – JESU Olugbala wa | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "JESU Olugbala wa" (C&S Hymn #715, Yoruba). JESU Olugbala wa, Awa fi iyin fun Ọ, Fun 'dasi ati 'pamọ Rẹ, Lori wa lat'…
JESU Olugbala wa, Awa fi iyin fun Ọ, Fun 'dasi ati 'pamọ Rẹ, Lori wa lat' esi; A tun pejọ loni yi, Lati yin orukọ Rẹ, Awa Ọmọ Ogun Kristi, Kérúbù, Séráfù, Awa n s'ajọdun wa, L'oni niwaju Rẹ, Ogo, iyin ọla ni fun Mẹtalọkan lailai. Baba Mimọ bukun wa, Ninu ajọdun yi, Fi Ẹmi Mimọ Rẹ fun wa, At'agbara Ẹmi, K'a le sin Ọ ni Mimọ; Gba wa lọwọ ẹsẹ, Ayé, esu, idanwo, Fun wa ni isẹgun. Ki 'mọlẹ wa ma tan, Bi 'lu lori oke, Ẹ jẹ k'a juba fun Jesu, Ọba wa olore Ẹyin Ọm' ogun Kristi, Ẹ ku ewu ọdun, Ẹ fun ipe Ọdaguntan, Ti Baba fi fun yin; Ẹyin ti ẹ n fi suru, Ru agbelebu yin, Ẹ o si jọba lailai, Nigba 'pọnju ba tan, Ipe 'kẹhin dun tan, Fun idajọ ayé, Onidajọ arayé yọ, O gunwa lori 'tẹ. Ọpọ ẹlẹgbẹ wa ni, Ko ri ọjọ oni, Ninu idamu ayé yi, Ọpọ ti sako lọ, Jesu n pe l'ohun jẹjẹ, Pe ỌMỌ ma sako, Pada ọmọ imọlẹ, Sinu agbo Jesu. Ẹ kede jake jado, Fun awọn Keferi, Pe, ọjọ Oluwa de tan, Ẹ ronupiwada. Ọlọrun ni Ẹlẹda, Ọrun ati ayé, O n fun itanna l'awọ, O n mu irawọ tan, Iji gba ohun rẹ gbọ; O n bọ awọn ẹyẹ, Papa awa ọmọ Rẹ, T'o n bo lojojumọ, Ẹbun rere gbogbo, Lati ọrun wa ni, A dupẹ lọwọ Ọlọrun, Fun gbogbo ifẹ Rẹ. Igba wa mbẹ l'ọwọ Rẹ, Nin' ọdun t'a wa yi, Ọm'ogun Kristi, ẹ gbadura, Mẹtalọkan y'o gbọ, Iwọ l'a n wo t'a si n sin, Ma jẹ k'oju tiwa, Ma jẹ k'awa ọmọ Rẹ, Sọkun ni ainidi. Iwọ la gbẹkẹle, Iwọ ni 'reti wa, Ran wa lọwọ k'a le sin Ọ De opin ẹmi wa. AMIN
Hymn 715 – JESU Olugbala wa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia