Hymn 702 – AJODUN wa l'a n se | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "AJODUN wa l'a n se" (C&S Hymn #702, Yoruba). AJỌDUN wa l'a n se, Aw'Ẹgbẹ Séráfù, Ajọdun wa l'a n se, Aw' Ẹgbẹ Kérúbù.…

Hymn 702 – AJODUN wa l'a n se | C&S Yoruba Hymnary
AJỌDUN wa l'a n se, Aw'Ẹgbẹ Séráfù, Ajọdun wa l'a n se, Aw' Ẹgbẹ Kérúbù. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. Kérúbù t'ayé yi, O fẹrẹ d'igi nla, Séráfù t'ayé yi, Ko le sai tan kiri. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. K'Ọlọrun b'asiri, Fun ọmọ Ẹgbẹ wa; K'ẹnikan ma rahun, Lati ri Ounjẹ jẹ. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. Ki esu ma ri wa, At'ẹni buburu, Ajẹ, oso, n se lasan, Lor' Ẹgbẹ Séráfù. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. Ẹmi airi n sọ wa, K'a ma ri ijọgbọn, Mase f'aye silẹ, Lati ma gbadura. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. Ohun buburu kan, Ko ri wa gbe se mọ, Gbogb' Ẹgbẹ agbayé, K'a s'otitọ d'opin. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. K'a n'ifẹ ara wa, K'ọkan wa k'o sọkan, K'a le ri 'bukun gba, 'Bukun lọpọlọpọ. Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun. Amin Arakunrin, Arabinrin, Ẹ ku ọdun, ẹ ku 'yedun.

Hymn 702 – AJODUN wa l'a n se | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia