Hymn 701 – AYE, e ba wa yo | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "AYE, e ba wa yo" (C&S Hymn #701, Yoruba). AYÉ, ẹ ba wa yọ, Ajọdun yi, o soju wa, Ẹ ba wa kọ'rin, Ẹ ba wa gbe'rin,…
AYÉ, ẹ ba wa yọ, Ajọdun yi, o soju wa, Ẹ ba wa kọ'rin, Ẹ ba wa gbe'rin, Onigbagbọ ẹ yọ, F'ore t'a ri gba l'ọfẹ, L'ọfẹ l'awa ri 'gbala. Gbogbo ayé, ẹ k'Alleluyah, K'a jọ yin Ọbangiji logo, Oun l'ọpẹ ati iyin yẹ fun, Ọpẹ, ọla ni fun Baba. Ẹgbẹ Igbimọ, Ẹ f'ogo fun Baba loke, Fun 'ranlọwọ Rẹ, Ninu ero yin, Ẹgbẹ Aladura, Ke Hosanna s'Ọba wa, Fun amure ododo. K'o fi di yin lọjọ oni yi , K'o si le ma gbọ adura yin, K'o ran Ẹmi Mimọ Rẹ si yin, Ni iru ọjọ oni. Ẹgbẹ Mose, Ati Ẹgbẹ Aaroni, F'ogo fun Baba, Ọmọ at'Ẹmi, Fun idapọ Ẹmi Mimọ t'o l'ogo, Fun 'jade wa oni yi, Halleluyah s'Olodumare, T'o da ẹmi wa si d'oni yi, K'o ran Olutunu Rẹ si wa, Ni iru ọjọ oni. Agbagba Mejila, Joseph ati Mary, Ẹgbẹ Esther, Akọni mejila, Ẹgbẹ Akọrin, Kérúbù oun Séráfù, D'orin pọ yin Ọba wa, Halleluyah s'Olodumare. T'o da ẹmi wa si d'oni yi, K'o ran Olutunu si wa, Ni iru ọjọ oni. Captin Abiọdun, F'ogo fun Baba loke, Ọmọ, Ẹmi Mimọ , Ke Halleluyah, Fun igbẹlẹke, Ju gbogbo ọta rẹ lọ, T'esu mọlẹ lẹsẹ rẹ. Gbogbo Irunmọlẹ ti subu Ajẹ, oso at'alawirin, Igunnu at'Ologun ika, Di itẹmọlẹ loni. N'ile Baba wa, Ọpọ ibugbe l'o wa, Ọlọrun Baba wa, Fun wa ni rere, N'ile Baba wa loke, Ogo fun Baba, Ọmọ, Ẹmi T'o pe wa sin' agbo mimọ yi, Layọ layọ la o wa nibẹ, N'ile Baba wa loke. AMIN
Hymn 701 – AYE, e ba wa yo | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia