Hymn 686 – OPO ikan omi | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OPO ikan omi" (C&S Hymn #686, Yoruba). ỌPỌ ikan omi, Yanrin kekeke; 'Wọnyi l'o d'okun nla, At' ile ayé. Isẹju wa…
ỌPỌ ikan omi, Yanrin kekeke; 'Wọnyi l'o d'okun nla, At' ile ayé. Isẹju wa kọkan, Ti a ko ka si, Lo d'ọdun aimọye, Ti ainipẹkun. Iwa ore diẹ, Ọrọ 'fẹ diẹ, L'o n s'ayé di Eden, Bi oke ọrun. Isisẹ kekeke, Lo n mọkan sina, Kuro l'ọna rere, Si ipa ẹsẹ. Isẹ anu diẹ, T'a se l'ọmọde, Di 'bukun f'orilẹ, To jina rere. Awọn ewe logo, N gberin Angẹli; Se wa yẹ, Oluwa, F'ẹgbẹ mimọ wọn. AMIN