Hymn 685 – OMODE, e sunm' Olorun | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OMODE, e sunm' Olorun" (C&S Hymn #685, Yoruba). ỌMỌDE, ẹ sunm' Ọlọrun, Pẹlu irẹlẹ at'ẹru; Ki ekun gbogbo wolẹ fun,…
ỌMỌDE, ẹ sunm' Ọlọrun, Pẹlu irẹlẹ at'ẹru; Ki ekun gbogbo wolẹ fun, Olugbala at'Ọrẹ wa. Oluwa, jẹ k'anu Rẹ nla, Mu wa kun fun ọpẹ si Ọ; Ati b'a ti n rin lọ l'ayé, K'a ma ri ọpọ anu gba. Oluwa! m'ero buburu, Jina rere si ọkan wa; L'ojojumọ fun wa l'ọgbọn, Lati yan ọna toro ni. Igba aisan at'ilera, Igba aini tabi ọrọ; Ati lakoko iku wa, Fi agbara Tirẹ gba wa. AMIN
Hymn 685 – OMODE, e sunm' Olorun | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia