Hymn 683 – OLORUN ogbon at'ore | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLORUN ogbon at'ore" (C&S Hymn #683, Yoruba). ỌLỌRUN ọgbọn at'ore, Tan 'mọlẹ at'otọ; Lati f'ọna totọ han wa, Lai tọ…

Hymn 683 – OLORUN ogbon at'ore | C&S Yoruba Hymnary
ỌLỌRUN ọgbọn at'ore, Tan 'mọlẹ at'otọ; Lati f'ọna totọ han wa, Lai tọ 'sisẹ wa. Lati tọ wa ninu ewu, Ni arin apata, Lati ma rin lọ larin wọn, K'a m'ọkọ wa gunlẹ B'or' ọfẹ Rẹ ti n mu wa ye, K'a kọ wọn b'eko Rẹ; Awa lati kọ ọmọ wa, Ni gbogbo ọna Rẹ. Ni akoko, pa ifẹ wọn, Oun 'gberaga wọn run! K'a fi ọna mimọ han wọn, Si Olugbala wọn. A fẹ woke nigbakugba, K'a tọ apẹrẹ Rẹ; K'a ru 'bẹru oun 'reti wọn, K'a tun ero wọn se. A fẹ rọ wọn lati gbagbọ, Ki wọn f'itara han; Ki a mase lo ikanra, 'Gba t'a ba le lo 'fẹ Eyi l'a f'igbagbọ bere, Ọgbọn t'o t'oke wa! K'a f'ẹru ọmọ s'aya wọn, Pẹlu ifẹ mimọ. K'a sọ 'fẹ wọn ti n tẹ s'ibi, Kuro l'ọna ewu; K'a fi pẹlẹ tẹ ọkan wọn, K'a fa wọn t'Ọlọrun. AMIN

Hymn 683 – OLORUN ogbon at'ore | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia