Hymn 662 – OLUWA n o ko nani wura ati fadaka | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "OLUWA n o ko nani wura ati fadaka" (C&S Hymn #662, Yoruba). OLUWA n ó ko nani wura ati fadaka, N ó mura lati d'ọrun…

Hymn 662 – OLUWA n o ko nani wura ati fadaka | C&S Yoruba Hymnary
OLUWA n ó ko nani wura ati fadaka, N ó mura lati d'ọrun lati wọ'nu agbo, Ninu iwe ijọba Rẹ ti ewe rẹ l'ẹwa, Sọ fun mi Olugbala, O‘ukọ mi ha wa n' ibẹ? O‘ukọ mi ha wa n'bẹ lara iwe funfun? Sọ fun mi Olugbala, O‘ukọ mi ha wa n'bẹ? Oluwa ẹsẹ mi pọ bi yanrin leti okun, Sugbọn ẹjẹ Olugbala o to lati wẹ mi, Nitori ileri Rẹ ki yẹ lai Oluwa, B'ẹsẹ yin pọn bi ododo, Yoo funfun bi sno. O‘ukọ mi ha wa n'bẹ lara iwe funfun? Sọ fun mi Olugbala, O‘ukọ mi ha wa n'bẹ? Ilu daradara ni at'ile didan rẹ, Pẹl' awọn t'a se logo to wọ asọ funfun, Ohun ibi ko si mbẹ la ti b'ẹwa rẹ jẹ, Nib'awọn Angeli n sọ, Okọ mi ha wa n' bẹ. O‘ukọ mi ha wa n'bẹ lara iwe funfun? Sọ fun mi Olugbala, O‘ukọ mi ha wa n'bẹ? AMIN O‘ukọ mi ha wa n'bẹ lara iwe funfun? Sọ fun mi Olugbala, O‘ukọ mi ha wa n'bẹ?

Hymn 662 – OLUWA n o ko nani wura ati fadaka | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia