Hymn 648 – SUNMOHIN, k'o gba Ara Oluwa | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "SUNMOHIN, k'o gba Ara Oluwa" (C&S Hymn #648, Yoruba). SUNMỌHIN, k'o gba Ara Oluwa, K'o mu Ẹjẹ mimọ t'a ta fun ọ. Ara…

Hymn 648 – SUNMOHIN, k'o gba Ara Oluwa | C&S Yoruba Hymnary
SUNMỌHIN, k'o gba Ara Oluwa, K'o mu Ẹjẹ mimọ t'a ta fun ọ. Ara at'ẹjẹ na l'o gba la, N' itura ọkan, f'ọpẹ f'Ọlọrun. Ẹlẹbun igbala, Ọmọ Baba Agbelebu Rẹ fun wa n'isẹgun. A fi Oun rubọ fun tagba tewe, Oun tikarẹ l'Ẹbọ, Oun l'Alufa. Gbogb' ẹbọ awọn Ju layé 'gbani, J'apẹrẹ ti n sọ t'Ẹbọ 'yanu yi Oun l'Oludande, Oun ni Imọlẹ Oun n f'Ẹmi ran awọn Tirẹ lọwọ. Njẹ, ẹ f'okan igbagbọ sunmọ 'hin, Ki ẹ si gba ẹri igbala yi. Oun l'o n sakoso eniyan Rẹ layé Oun l'o n f'iye ainipẹkun fun wa. O n f'Ounjẹ ọrun f'awọn t'ebi n pa, Omi iye fun ọkan n poungbẹ. Onidajọ wa, Olugbala wa, Pẹlu wa ni ase ifẹ Rẹ yi. AMIN

Hymn 648 – SUNMOHIN, k'o gba Ara Oluwa | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia