Hymn 647 – OLUGBALA a de loni | C&S Yoruba Hymnary
Read, copy, and download the lyrics of "OLUGBALA a de loni" (C&S Hymn #647, Yoruba). OLUGBALA a de loni, Lati wa da Majẹmu; Ran Ẹmi Iye Rẹ si wa, K'O so…
OLUGBALA a de loni, Lati wa da Majẹmu; Ran Ẹmi Iye Rẹ si wa, K'O so gbogbo wa dọtun. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. Wa tun 'bajẹ inu wa se, F'ara Rẹ han wa loni; Ma jẹ ki Esu ba wa pe, Ran Ẹmi Rẹ s'arin wa. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. Ẹmi Agbara sọkalẹ, F'ọwọ Ifẹ yi wa ka; Ka sinmi le ileri Rẹ, Ka mase siyemeji. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. Ma jẹ ki ifẹ wa tutu, Larin Ẹgbẹ Mimọ yi, Ka le fa ọpọ aguntan, Si'nu agbo Mimọ yi. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. Baba wa gbọ tiwa loni, Sọkalẹ nin'ọla Rẹ; Lati wa ya wa si mimọ, K'Ẹmi Mimọ ba le wa. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. Ẹ f'ogo fun Baba l'oke, Ẹ f'ogo fun Ọmọ Rẹ; Ogo ni fun Ẹmi Mimọ , Ogun fun Mẹtalọkan. Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe. AMIN Ẹmi Mimọ sọkalẹ wa, Wa fi agbara Rẹ han, Olugbala, Olugbala; Olugbala, ba wa pe.
Hymn 647 – OLUGBALA a de loni | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia