Hymn 633 – TIRE titi lai l'awa se | C&S Yoruba Hymnary

Read, copy, and download the lyrics of "TIRE titi lai l'awa se" (C&S Hymn #633, Yoruba). TIRẸ titi lai l'awa se, Oluwa wa ọrun; K'ohun at'ọkan wa wi pé, Amin,…

Hymn 633 – TIRE titi lai l'awa se | C&S Yoruba Hymnary
TIRẸ titi lai l'awa se, Oluwa wa ọrun; K'ohun at'ọkan wa wi pé, Amin, bẹni k'o ri. Gba ti ayé ba n dun mọ ni, T'o si n fa ọkan wa; K'iro yi pe, Tirẹ l'awa Le ma dun l'eti wa. 'Gba t'ẹsẹ pẹlu ẹtan rẹ, Ba fẹ se wa n'ibi; K'iro yi pe, Tirẹ l'awa. Tu ẹtan ẹsẹ ka. 'Gba ti Esu ba n tafa rẹ, S'ori ailera wa; K'iro yi pe, Tirẹ l'awa, Ma jẹ ki o rẹ wa. Tirẹ, n' igb' a wa l'ọmọde, Tirẹ, n' igb' a ndagba, Tirẹ, n' igb'a ba darugbo, Ti ayé wa n buse. Tirẹ, titi lai l'awa se, A f'ara wa fun Ọ: Titi ayé ainipẹkun, Amin, bẹni k'o ri. AMIN

Hymn 633 – TIRE titi lai l'awa se | C&S Yoruba Hymnary on Seraphmedia